Matthew 22:41-45

Ọmọ ta ni Kristi?

41 aBí àwọn Farisi ti kó ara wọn jọ, Jesu béèrè lọ́wọ́ wọn pé, 42“Kí ni ẹ rò nípa Kristi? Ọmọ ta ni òun ń ṣe?”

Wọ́n dáhùn pé, “Ọmọ Dafidi.”

43Ó sì wí fún wọn pé, “Kí lo dé tí Dafidi, tí ẹ̀mí ń darí, pè é ní ‘Olúwa’? Nítorí ó wí pé,

44 “ ‘Olúwa sọ fún Olúwa mi pé,
“Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi
títí tí èmi yóò fi fi àwọn ọ̀tá rẹ
sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ.” ’
45 Ǹjẹ́ bí Dafidi bá pè é ni ‘Olúwa,’ báwo ni òun ṣe lè jẹ́ ọmọ rẹ̀?”
Copyright information for YorBMYO